Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Antichrist

14 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.

  2. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

  3. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.

  4. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.

  5. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé.

  6. Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.

  7. Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín.

  8. Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an.

  9. Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà.

  10. Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun.

  11. Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì àmì àti àdàmọ̀dì idán,

  12. ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà.

  13. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́,

  14. kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.