Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Amusements and Worldly Pleasures

18 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn ìjòyè, àwọn ará Filistini sì péjọpọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dagoni ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Samsoni ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́.

  2. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Samsoni wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé, “Ọlọ́run wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́. Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”

  3. Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Samsoni wá kí ó wá dá wa lára yá. Wọ́n sì pe Samsoni jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn. Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàrín àwọn òpó.

  4. Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti haapu; wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè.

  5. Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

  6. Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.

  7. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

  8. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti lépa ọtí líle, tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́ títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.

  9. Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn, ṣaworo òun fèrè àti wáìnì, ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

  10. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.

  11. Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini. Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?

  12. Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.

  13. Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.

  14. Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.

  15. Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.

  16. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi.

  17. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.

  18. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”.