Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aliens: To be treated with justice

13 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ nípa To be treated with justice

  1. “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì ni ilẹ̀ Ejibiti rí.

  2. “Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.

  3. “ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi

  4. kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  5. Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé, ẹ gbọ́ èdè-àìyedè tí ó wà láàrín àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrín Israẹli sí Israẹli ni tàbí láàrín Israẹli kan sí àlejò.

  6. Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwọn àjèjì, torí pé ẹ̀yin pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì rí ní Ejibiti.

  7. Má ṣe ni alágbàṣe kan lára tí ó jẹ́ tálákà àti aláìní, bóyá ó jẹ́ arákùnrin Israẹli tàbí àlejò tí ó ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ.

  8. Má ṣe yí ìdájọ́ po fún àlejò tàbí aláìní baba, tàbí gba aṣọ ìlekè opó bí ẹ̀rí.

  9. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

  10. Bí ẹ kò bá fi ara ni àwọn àlejò, àwọn ọmọ aláìní baba àti àwọn opó tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, bí ẹ kò bá sì tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìpalára ara yín.

  11. Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.

  12. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

  13. “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.