Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ablution: Of the hands
Àwọn ẹsẹ nípa Of the hands
“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.
Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.
Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa,
wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.”
Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,
Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn.
Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.