circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Johanu 10:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.
- Johanu 10:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó.
- Johanu 10:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ àmì kan, Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”
- Johanu 10:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.
- Johanu 11:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀.
- Johanu 11:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá.
- Johanu 11:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”
- Johanu 11:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”
- Johanu 11:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.
- Johanu 11:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà.
- Johanu 11:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
- Johanu 11:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”
- Johanu 11:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.
- Johanu 11:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”
- Johanu 11:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ, lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”
- Johanu 11:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.”
- Johanu 11:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.
- Johanu 11:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú.
- Johanu 11:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”
- Johanu 11:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”
- Johanu 11:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná,
- Johanu 11:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
- Johanu 11:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.
- Johanu 11:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.
- Johanu 11:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.