Fò sí àkóónú

Jerusalem

753 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jerusalem's

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jerusalem

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu.

  2. Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Benjamini àti ní ìlú kéékèèké tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda àti ní ìlú àwọn ìlú orí òkè, àti ni àwọn ẹsẹ̀ òkè, àti ní gúúsù, èmi ó mú ìgbèkùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”

  3. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí.

  4. Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

  5. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Juda yóò di ẹni ìgbàlà. Jerusalẹmu yóò sì máa gbé láìséwu. Orúkọ yìí ni a ó máa pè é Olúwa wa olódodo.’

  6. Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa pé:

  7. Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu.

  8. Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda.

  9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.

  10. Àwọn ìjòyè Juda àti àwọn ti Jerusalẹmu, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrín àwọn ìpín méjèèjì ẹgbọrọ màlúù náà.

  11. Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

  12. “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

  13. “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

  14. Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda.

  15. Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”

  16. Àwọn ọmọ-ogun Farao ti jáde kúrò nílẹ̀ Ejibiti àti nígbà tí àwọn ará Babeli tó ń ṣàtìpó ní Jerusalẹmu gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.

  17. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ-ogun Babeli ti kúrò ní Jerusalẹmu nítorí àwọn ọmọ-ogun Farao.

  18. Jeremiah múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Benjamini láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrín àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀.

  19. Jeremiah wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jerusalẹmu:

  20. Ó sì ṣe, nígbà tí a kó Jerusalẹmu, ní ọdún kẹsànán Sedekiah, ọba Juda, nínú oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun ti Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, wọ́n sì dó tì í.

  21. Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu.

  22. Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli.

  23. Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’

  24. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun.

  25. Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.