Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Nítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”
Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”
Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.” Nítorí náà ni àwọn Júù wí fún un pé, “Kò tọ́ fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”
Kí ọ̀rọ̀ Jesu ba à lè ṣẹ, èyí tí ó sọ tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.
Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”
Jesu dáhùn pé, “Èrò ti ara rẹ ni èyí, tàbí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ́ fún ọ nítorí mi?”
Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́, kín ní ìwọ ṣe?”
Jesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”
Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”
Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.
Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.
Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án.
Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́.
Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.
Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”
Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ọkùnrin náà!”
Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”
Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”
Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn.
Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”
Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá, nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”
Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”
Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jesu jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Heberu, Gabata.
Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.”
Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.