Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí?

  2. Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà?

  3. Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá, ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

  4. Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá, èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀.

  5. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

  6. Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

  7. Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

  8. Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

  9. Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.

  10. Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

  11. Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí.

  12. Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ‘Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi,’ àti ‘Ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà’?”

  13. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.

  14. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”

  15. Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà, nítorí a kò tí ì fi Èmí Mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.

  16. Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.” Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí?

  17. Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”

  18. Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.

  19. Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

  20. Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

  21. Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

  22. Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí?

  23. Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,

  24. Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

  25. Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn.