Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli:
Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu,
Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn;
Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.
Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí Ọmọ Ènìyàn.
“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi, ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín.
Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.
Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?
“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí?
Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín.
Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ.
Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.
Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún.
Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi.
Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá.
Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.”
Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.
Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”
Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”
Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”
Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”