Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

  2. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  3. Olúwa sọ fún Mose pé,

  4. Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.

  5. Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.

  6. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Ejibiti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

  7. Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ?”

  8. Ó sì sọ fún Kora àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ àti ẹni tó mọ́ hàn, yóò sì mú kí ẹni náà súnmọ́ òun. Ẹni tí ó bá yàn ni yóò mú kí ó súnmọ́ òun.

  9. Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú Olúwa, yóò sì ṣe, ọkùnrin tí Olúwa bá yàn òun ni. Ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ti kọjá ààyè yín!”

  10. Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Israẹli ti yà yín sọ́tọ̀ lára ìjọ Israẹli yòókù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?

  11. Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Lefi súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà.

  12. Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

  13. Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”

  14. Mose sọ fún Kora pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Aaroni.

  15. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta lé nígba (250) àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”

  16. Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.

  17. Olúwa sì sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  18. “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín ìjọ wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”

  19. Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?”

  20. Olúwa tún sọ fún Mose pé,

  21. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.

  22. Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yòókù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.

  23. Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”

  24. Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin tí wọ́n mú tùràrí wá.

  25. Olúwa sọ fún Mose pé,