God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ǹjẹ́ èmi ha ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní Olúwa Olódùmarè wí pé, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ kí ó sì yè?
“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin tún wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ ilé Israẹli. Ọ̀nà mi ni kò ha gún? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà tiyín gan an ni kò gún?
Síbẹ̀, ilé Israẹli wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí ilé Israẹli? Kì í wa ṣe pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko gún?
“Nítorí náà, ilé Israẹli, èmi yóò da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ẹ yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ìrékọjá kì yóò jẹ́ ọ̀nà ìṣubú yín.
Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!
Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ Olúwa, wọn jókòó níwájú mi.
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’
kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.
Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
“ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti.
Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti.
Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù.
Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.
Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.
“ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.
Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde.
Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.
Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.
Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù.
Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín, ẹ má ṣe pa òfin wọn mọ́, ẹ má ṣe bá ara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.
Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrín wa, ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù.