Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah.

  2. Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.

  3. Àwọn ènìyàn náà lọ sí Beteli: ilé Ọlọ́run, níbi tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run títí di àṣálẹ́, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún kíkorò.

  4. Wọ́n sọkún wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run Israẹli, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Israẹli? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Israẹli lónìí?”

  5. Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti péjọ síwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mispa pípa ni àwọn yóò pa á.

  6. Báwo ni a yóò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya.

  7. Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà.

  8. Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

  9. Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lebona.”

  10. Nígbà tí Naomi gbọ́ ní Moabu tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fífún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀.

  11. Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Naomi wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.

  12. Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.” Naomi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” wọ́n sì sọkún kíkankíkan.

  13. ẹ̀yin ha le è dúró dìgbà tí wọ́n yóò fi dàgbà? Ẹ̀yin ó le è dúró dè wọ́n láì fẹ́ ọkọ mìíràn? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, nítorí pé inú mi bàjẹ́ gidigidi ju tiyín lọ, nítorí tí ọwọ́ Olúwa fi jáde sí mi!”

  14. Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.

  15. Níbi tí ìwọ bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí Olúwa jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.”

  16. Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi mọ́, ẹ pè mí ní Mara, nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò.

  17. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n Olúwa mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kín ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”

  18. Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí Olúwa wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ.”

  19. Kí Olúwa kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”

  20. Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.”

  21. Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.

  22. Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí Olúwa ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.”

  23. Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu.

  24. Kí Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Peresi ọmọkùnrin tí Tamari bí fún Juda láti ipasẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”

  25. Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, Olúwa sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan.