Òwe 23:15-35
15
Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.
16
Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.
17
Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa, ní ọjọ́ gbogbo.
18
Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́; ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.
19
Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20
Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;
21
nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
22
Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.
23
Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.
24
Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.
25
Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.
26
Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.
27
Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni; àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.
28
Òun á sì ba ní bùba bí olè, a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.
29
Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́? Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?
30
Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.
31
Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.
32
Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.
33
Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.
34
Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun, tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.
35
Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí; wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀: nígbà wo ni èmi ó jí? Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings