- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Òwe àwọn agbéyàwó búburú
Matiu 21:33-46
Òwe àwọn agbéyàwó búburú
33
“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.
34
Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.
35
“Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta.
36
Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
37
Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’
38
“Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’
39
Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.
40
“Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?”
41
Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”
42
Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?
43
“Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.
44
Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
45
Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi gbọ́ òwe Jesu, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn.
46
Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jesu gẹ́gẹ́ bí wòlíì.
Kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ wọ̀nyí
Àlàyé lórí gbogbo ẹsẹ wọ̀nyí, kì í ṣe ẹsẹ kan ṣoṣo
- Ta ni
- Níbo
- Ìgbà wo
- About
Ibi mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ èyí
Saamu 118:22
Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé;láti ẹsẹ 42Saamu 118:23
Olúwa ti ṣe èyí, ó ṣe ìyanu ní ojú wa.láti ẹsẹ 42Isaiah 28:16
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.láti ẹsẹ 42Ìṣe àwọn Aposteli 4:11
Èyí ni “ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’láti ẹsẹ 421 Peteru 2:4
Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye.láti ẹsẹ 421 Peteru 2:8
àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.láti ẹsẹ 42Efesu 2:20
a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé.láti ẹsẹ 42Romu 9:33
Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”láti ẹsẹ 42Isaiah 8:14
Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.láti ẹsẹ 44Isaiah 8:15
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀, wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá, okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”láti ẹsẹ 44Isaiah 5:1
Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.láti ẹsẹ 33Isaiah 5:4
Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan?láti ẹsẹ 33



Àkọsílẹ̀ Ẹ̀kọ́
Settings