Luku 1:57-80
57
Nígbà tí ọjọ́ Elisabeti pé tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.
58
Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.
59
Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sekariah, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.
60
Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Johanu ni a ó pè é.”
61
Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”
62
Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.
63
Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.
64
Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.
65
Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn, a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Judea.
66
Ó sì jẹ́ ohun ìyanu fún gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì tò ó sínú ọkàn wọn, wọ́n ń wí pé, “Irú-ọmọ kín ni èyí yóò jẹ́?” Nítorí tí ọwọ́ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.
67
Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:
68
“Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli; nítorí tí ó ti bojú wò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,
69
Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún wa ní ilé Dafidi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀;
70
(bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),
71
Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.
72
Láti ṣe àánú tí ó ṣèlérí fún àwọn baba wa, àti láti rántí májẹ̀mú rẹ̀ mímọ́,
73
ìbúra tí ó ti bú fún Abrahamu baba wa,
74
láti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí àwa kí ó lè máa sìn láìfòyà,
75
ni ìwà mímọ́ àti ní òdodo níwájú rẹ̀, ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
76
“Àti ìwọ, ọmọ mi, wòlíì Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó máa pè ọ́: nítorí ìwọ ni yóò ṣáájú Olúwa láti tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe;
77
láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78
nítorí ìyọ́nú Ọlọ́run wà; nípa èyí tí ìlà-oòrùn láti òkè wá bojú wò wá,
79
Láti fi ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó jókòó ní òkùnkùn àti ní òjìji ikú, àti láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà àlàáfíà.”
80
Ọmọ náà sì dàgbà, ó sì le ní ọkàn, ó sì ń gbé ní ijù títí ó fi di ọjọ́ ìfihàn rẹ̀ fún Israẹli.
Settings