Skip to content
Esekiẹli 23:1-32

Esekiẹli 23:1-32

1
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2
“Ọmọ ènìyàn, obìnrin méjì wà, ọmọ ìyá kan náà.
3
Wọn ń ṣe panṣágà ní Ejibiti, wọn ń ṣe panṣágà láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.
4
Èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Oholiba. Tèmi ni wọ́n, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ohola ni Samaria, Oholiba sì ni Jerusalẹmu.
5
“Ohola ń ṣe panṣágà nígbà tí ó sì jẹ́ tèmi; Ó sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn jagunjagun ará Asiria.
6
Aṣọ aláró ni a fi wọ̀ wọ́n, àwọn gómìnà àti àwọn balógun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà àwọn tí ń gun ẹṣin.
7
O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,
8
kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
9
“Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.
10
Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pa wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrín àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.
11
“Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.
12
Òun náà ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ará Asiria àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.
13
Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.
14
“Ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe panṣágà. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kaldea àwòrán pupa,
15
pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Babeli ọmọ ìlú Kaldea.
16
Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán oníṣẹ́ sí wọn ni Kaldea.
17
Àwọn ará Babeli wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ibùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.
18
Nígbà tí ó tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ panṣágà rẹ̀ ní gbangba wọ́n sì tú u sí ìhòhò, mo yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìtìjú, gẹ́gẹ́ bí mo ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
19
Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ panṣágà ní Ejibiti.
20
Nítorí ó fẹ́ olùfẹ́ àwọn olùfẹ́ wọn ní àfẹ́jù, tí àwọn tí nǹkan ọkùnrin wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn ẹni tí ìtújáde ara wọn dàbí ti àwọn ẹṣin.
21
Báyìí ni ìwọ pe ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ wá sí ìrántí, ní ti rírin orí ọmú rẹ láti ọwọ́ àwọn ará Ejibiti, fún ọmú ìgbà èwe rẹ.
22
“Nítorí náà, Oholiba, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò gbé olólùfẹ́ rẹ dìde sí ọ, àwọn tí o kẹ́yìn si ní ìtìjú, èmi yóò sì mú wọn dojúkọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà
23
àwọn ará Babeli àti gbogbo ara Kaldea àwọn ọkùnrin Pekodi àti Ṣoa àti Koa àti gbogbo ará Asiria pẹ̀lú wọn, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà, gbogbo àwọn gómìnà àti balógun, olórí oníkẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn onípò gíga, gbogbo àwọn tí ń gun ẹṣin.
24
Wọn yóò wa dojúkọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú asà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àṣíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.
25
Èmi yóò sì dojú ìbínú owú mi kọ ọ́, wọn yóò sì fìyà jẹ ọ́ ní ìrunú. Wọ́n yóò gé àwọn imú àti àwọn etí yín kúrò, àwọn tí ó kù nínú yín yóò ti ipá idà ṣubú. Wọn yóò mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin yín lọ, àwọn tí o kù nínú yín ni iná yóò jórun.
26
Wọn yóò sì kó àwọn aṣọ àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yín.
27
Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ panṣágà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Ejibiti. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìpòùngbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Ejibiti mọ.
28
“Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi ọ lé ọwọ́ àwọn tí ó kórìíra, lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ọkàn rẹ ti ṣí kúrò.
29
Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ panṣágà rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti panṣágà rẹ.
30
Èmi yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ọ, nítorí ìwọ ti bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè lọ, o sì fi àwọn òrìṣà wọn ba ara rẹ̀ jẹ́.
31
Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn, Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.
32
“Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ, ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú: yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options