Deuteronomi 3:1-13
1
Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei.
2
Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. Kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”
3
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè.
4
Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta ìlú tí wọ́n ní, gbogbo agbègbè Argobu, lábẹ́ ìjọba Ogu ní Baṣani.
5
Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kéékèèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú.
6
Gbogbo wọn ni a parun pátápátá gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Sihoni ọba Heṣboni, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátápátá: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn.
7
Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú wọn, fún ara wa.
8
Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jordani láti odò Arnoni, títí dé orí òkè Hermoni lọ́wọ́ àwọn ọba Amori méjèèjì wọ̀nyí.
9
(Àwọn ará Sidoni ń pe Hermoni ní Sirioni. Àwọn Amori sì ń pè é ní Seniri).
10
Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gileadi, àti gbogbo Baṣani, títí dé Saleka, àti Edrei, ìlú àwọn ọba Ogu ní ilẹ̀ Baṣani.
11
(Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.)
12
Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Aroeri níbi odò Arnoni, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gileadi pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.
13
Gbogbo ìyókù Gileadi àti gbogbo Baṣani, ní ilẹ̀ ọba Ogu ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase. (Gbogbo agbègbè Argobu ni Baṣani tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Refaimu.
Settings