Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Truth of God

40 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.

  2. Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.

  3. Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

  4. Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi; èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

  5. Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

  6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.

  7. Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.

  8. Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.

  9. Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.

  10. Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kristi. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípasẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.

  11. ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,

  12. Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.

  13. Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.

  14. Wọ́n sì ń kọ orin ti Mose, ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àti orin ti Ọ̀dọ́-Àgùntàn, wí pé: “Títóbi àti ìyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè; òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀nà rẹ̀, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè.

  15. Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”