Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Pharisees: Zealous of tradition

6 ẹsẹ · 42 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Zealous of tradition

  1. (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.

  2. Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”

  3. Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.

  4. Ìsìn wọn jẹ́ lásán, ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

  5. Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”

  6. Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.