Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Afflictions of the Wicked

95 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.

  2. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”

  3. “Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́. Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀. Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá.

  4. Èmi wí fún ìlú náà wí pé, ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́.

  5. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

  6. Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.

  7. “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́.

  8. Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  9. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

  10. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si.

  11. Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.”

  12. Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹgbẹ̀rún (23,000) ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan.

  13. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

  15. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá.

  16. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,

  17. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run.

  18. Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.

  19. Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.

  20. Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Babeli ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’