Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Slothfulness

38 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún wà lójú ọ̀nà kìnnìún búburú ń ké ní ojú ọ̀nà.”

  2. Bí ìlẹ̀kùn ti ń yí lórí ìsolẹ̀kùn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí lórí ibùsùn rẹ̀.

  3. Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ, ó lẹ dé bi pé kò le è mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.

  4. Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.

  5. Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.

  6. Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.

  7. “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí.

  8. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

  9. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa.

  10. Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

  11. A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri.

  12. Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.

  13. Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.