Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Self-Crimination: General references

20 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. Olúwa sọ fún Mose wí pé,

  2. “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìṣòótọ́ sí i,

  3. nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lòpọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).

  4. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ dé bi pé ó ń funra sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,

  5. nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n efa ìyẹ̀fun barle. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

  6. “ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa.

  7. Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀.

  8. Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.

  9. Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi.

  10. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,”

  11. nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé, “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú.

  12. Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.” “ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”

  13. “ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà.

  14. Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.

  15. Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.

  16. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.

  17. Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  18. “Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lé e láti mú un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí,

  19. nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.

  20. olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.