Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Salt

32 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.

  2. Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí, “nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu, àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra, ibi tí ó kún fún yèrèpè, àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”

  3. “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

  4. Níbẹ̀ ni a ó ti fi iná dán ẹnìkọ̀ọ̀kan wò.

  5. “Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mú un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”

  6. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

  7. Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù.