Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rachel

58 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Labani sì lọ sínú àgọ́ Jakọbu àti ti Lea àti ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Lea ni ó lọ sí àgọ́ Rakeli.

  2. Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun.

  3. Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà.

  4. Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi, torí pé ó ń kú lọ, ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni, ọmọ ìpọ́njú. Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini, ọmọ oókan àyà mi.

  5. Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (ti o túmọ̀ sí, Bẹtilẹhẹmu).

  6. Jakọbu sì mọ ọ̀wọ́n kan sí ibojì rẹ̀, ọ̀wọ̀n náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rakeli títí di òní.

  7. Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu).

  8. Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Selsa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’