- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Public Prayer
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí,
ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’;
tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé Olúwa tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ;
nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.
“Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, Olúwa Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmì òróró rẹ.
tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn.
Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.
Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.
O sì wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.
Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?
Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé,
‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run.
Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní.
Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”
Gbogbo àwọn ọkùnrin Juda, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kéékèèké, dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọpọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn.
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú gbogbo àwọn àjèjì. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn.
Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin Olúwa Ọlọ́run wọn.
Nígbà náà ni Jeṣua, àti Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani àti Kenaani gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn.
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé, “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.
Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.
“Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Abramu tí ó sì mú u jáde láti Uri ti Kaldea, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Abrahamu.