Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Proselytes

31 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn Giriki kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ,

  2. Frigia, àti Pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù

  3. Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku.

  4. Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn,

  5. Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

  6. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila, bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.