Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peace Offerings

70 ẹsẹ · 38 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Bí ẹni náà bá gbé e wá gẹ́gẹ́ bí àfihàn ọkàn ọpẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọpẹ́ yìí, ó gbọdọ̀ mú àkàrà aláìwú tí a fi òróró pò wá àti àkàrà aláìwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a dà òróró sí àti àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò ṣe.

  2. Pẹ̀lú ọrẹ àlàáfíà rẹ̀, kí ó tún mú àkàrà wíwú wá fún ọpẹ́,

  3. Ẹran ọrẹ àlàáfíà ti ọpẹ́ yìí ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ ní ọjọ́ gan an tí wọ́n rú ẹbọ, kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ẹran kankan kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.

  4. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ó mú ọrẹ wá, nítorí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ tàbí kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, wọn yóò jẹ ẹbọ náà ní ọjọ́ tí wọ́n rú ẹbọ yìí, ṣùgbọ́n wọ́n lè jẹ èyí tó ṣẹ́kù ní ọjọ́ kejì.

  5. Gbogbo ẹran tó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ní ẹ gbọdọ̀ sun.

  6. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.

  7. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

  8. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa.

  9. Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífì.

  10. Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀,

  11. kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà.

  12. Ọmọ Aaroni ẹni tí ó rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.

  13. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’ ”

  14. Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  15. àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”

  16. “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín.

  17. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun.

  18. Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

  19. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  20. Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù.

  21. Lẹ́yìn náà kí ẹ fi akọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan fún ọrẹ àlàáfíà.

  22. Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà,

  23. akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  24. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.

  25. Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”