Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peace Offerings

70 ẹsẹ · 38 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀.

  2. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.

  3. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.)

  4. Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.

  5. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

  6. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa.

  7. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

  8. “Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.

  9. Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

  10. “Aṣọ mímọ́ Aaroni yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́.

  11. “ ‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú Olúwa.

  12. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

  13. Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn.

  14. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

  15. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

  16. “ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.

  17. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

  18. Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.

  19. Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.

  20. “ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.

  21. Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.

  22. Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti Olúwa.

  23. Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀.

  24. Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.

  25. “ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún ọrẹ àlàáfíà tí ẹnikẹ́ni bá gbé wá síwájú Olúwa.