Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Moabites: Their desolation as a punishment for their hatred of Israel
Àwọn ẹsẹ nípa Their desolation as a punishment for their hatred of Israel
“Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa, jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn.
Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,”
nítorí náà, Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu.