Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Moabites: Conquered by Israel and Judah

3 ẹsẹ · 56 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Conquered by Israel and Judah

  1. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Moabu dé sí ibùdó ti Israẹli, àwọn ará Israẹli dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ. Àwọn ará Israẹli gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Moabu run.

  2. Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run. Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára. Kiri-Hareseti nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní ààyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kànnàkànnà yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà.

  3. Nígbà tí ọba Moabu rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) ọkùnrin onídà láti jà pẹ̀lú ọba Edomu, ṣùgbọ́n wọn kò yege.