Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Midianites: Retained the knowledge and worship of Jehovah

5 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Retained the knowledge and worship of Jehovah

  1. Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.

  2. Inú Jetro dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Israẹli, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

  3. Jetro sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti àti lọ́wọ́ Farao, ẹni tí ó sì gba àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti.

  4. Mo mọ nísinsin yìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Ejibiti.”

  5. Jetro, àna Mose, mú ẹbọ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Aaroni àti gbogbo àgbàgbà Israẹli sì wá láti bá àna Mose jẹun ní iwájú Ọlọ́run.