Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Integrity

96 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.

  2. Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ bá à lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.

  3. Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

  4. Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre; títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.

  5. Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.

  6. “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?

  7. Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.

  8. Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

  9. Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

  10. “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,

  11. (jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

  12. Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,

  13. ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

  14. “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,

  15. kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.

  16. Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.

  17. Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.

  18. “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;

  19. kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?

  20. Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?

  21. “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

  22. tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;

  23. nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:

  24. bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí tálákà kan láìní ìbora;

  25. bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;