Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Gluttony: General references

18 ẹsẹ · 15 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.

  2. Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí oòrùn bá sì mú, a sì yọ́.

  3. Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí, ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.

  4. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrín eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn.

  5. Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.”

  6. Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

  7. “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

  8. Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,

  9. Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.

  10. Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.

  11. Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.

  12. Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.

  13. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

  14. “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

  15. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara:

  16. Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.

  17. Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara.

  18. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.