Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Forsaking God

25 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Ejibiti lábẹ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn,

  2. wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Israẹli tí ó ti paláṣẹ.

  3. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìṣọ́ sí ìlú tí a dáàbò bò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.

  4. Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀ sókè àti ère òrìṣà Aṣerah lórí gbogbo igi tútù.

  5. Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búburú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè.

  6. Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”

  7. Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

  8. Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́rùn líle gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́.

  9. Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

  10. Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbẹ́ ẹ ọ̀kan ní ère ẹgbọrọ màlúù, àti ọ̀kan ní ère òrìṣà Aṣerah. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Baali.

  11. Wọ́n sì fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn rú ẹbọ nínú iná. Wọ́n sì ń fọ àfọ̀ṣẹ, wọ́n sì ń ṣe àlúpàyídà wọ́n sì ta ara wọn láti ṣe ohun búburú níwájú Olúwa, wọ́n sì mú un bínú.

  12. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì bínú gidigidi pẹ̀lú Israẹli ó sì mú wọn kúrò níwájú rẹ̀. Ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo ni ó kù,

  13. gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin Olúwa, wa mọ́ dáradára.

  14. “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

  15. “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́.

  16. “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé, a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa:

  17. nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

  18. “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin.

  19. “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé Olúwa.

  20. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

  21. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.

  22. Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra.

  23. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”

  24. Báyìí ni Olúwa wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi, tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnra wọn sì di asán.

  25. Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà, tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, tí ó mú wa la aginjù já, tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò, ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’