Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fear of God

31 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á.

  2. A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”

  3. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù.

  4. Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

  5. Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

  6. Ẹ bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ sì máa sìn ín. Ẹ dìímú ṣinṣin, kí ẹ sì búra ní orúkọ rẹ̀.

  7. Òun ni ìyìn in yín, Òun sì ni Ọlọ́run yín, tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá àti ohun ẹ̀rù, tí ẹ fojú ara yín rí.

  8. Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.

  9. Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.

  10. Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.

  11. Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

  12. Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

  13. Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta àti sínú ihò ilẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

  14. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán.

  15. Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

  16. Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn.

  17. Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn, Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.

  18. Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n, nínú gbogbo agbára wọn. Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn, etí wọn yóò sì di.

  19. Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.

  20. Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.

  21. Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́,

  22. nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.”

  23. Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”

  24. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye,

  25. si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé,