Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Dreams: God the only interpreter of

4 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ nípa God the only interpreter of

  1. Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún

  2. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

  3. “Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

  4. Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.