Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Church of Israel

34 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà.

  2. Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín.

  3. Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ.

  4. Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.

  5. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.”

  6. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.

  7. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má ba à ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrín wọn.”

  8. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

  9. Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.

  10. Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”

  11. Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkígbà tí a bá ń ké pè é?

  12. Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

  13. Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

  14. Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

  15. Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri.

  16. Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.

  17. Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì.

  18. Olúwa sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á.

  19. Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ Olúwa wá.

  20. Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.

  21. Kí ọmọ Ammoni tàbí ọmọ Moabu, kì yóò wọ ìjọ Olúwa, àní títí dé ìran kẹwàá, ènìyàn wọn kan kì yóò wọ inú ìjọ ènìyàn Olúwa láéláé.

  22. Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Ejibiti àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégùn ún Balaamu ọmọ Beori ará a Petori ti Aramu-Naharaimu.

  23. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli.

  24. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.”

  25. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara ni ọmọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ.