- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Christian Conduct
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ Olúwa dájú òdodo ni gbogbo wọn.
Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ.
Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú.
Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé.
Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
Alábùkún fún ni àwọn aláàánú, nítorí wọn yóò rí àánú gbà.
Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.
Alábùkún fún ni àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.
Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.
“Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.
Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.
Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú.
Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.
Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.
Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá.
Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn.
Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni i ṣe fún ọ́ sí rere. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣé búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò gbé idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní í ṣe, olùgbẹ̀san láti ṣiṣẹ́ ìbínú lára ẹni tí ń ṣe búburú.
Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú.
Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo.