Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Birds: (Snaring,) of designs of the wicked

8 ẹsẹ · 107 abala

Àwọn ẹsẹ nípa (Snaring,) of designs of the wicked

  1. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.

  2. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

  3. jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

  4. a ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa,

  5. da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà,”

  6. ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn.

  7. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

  8. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ àwọ̀n sílẹ̀, ní ojú ẹyẹ!