Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Birds: Appointed for food

12 ẹsẹ · 107 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Appointed for food

  1. Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

  2. Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

  3. Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.

  4. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,

  5. onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,

  6. onírúurú ẹyẹ ìwò,

  7. ògòǹgò, òwìwí, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,

  8. onírúurú òwìwí,

  9. òwìwí ọ̀dàn, àkàlà, ìgò,

  10. àkọ̀, òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.

  11. Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rìn jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.

  12. Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyìí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.