Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 18:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára.

  2. Luku 18:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”

  3. Luku 18:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn, ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.

  4. Luku 18:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe.

  5. Luku 18:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí.

  6. Luku 18:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”

  7. Luku 18:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

  8. Luku 18:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

  9. Luku 18:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í

  10. Luku 18:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

  11. Luku 18:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”

  12. Luku 18:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.

  13. Luku 19:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀.

  14. Luku 19:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.

  15. Luku 19:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.

  16. Luku 19:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.

  17. Luku 19:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.”

  18. Luku 19:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.

  19. Luku 19:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”

  20. Luku 19:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”

  21. Luku 19:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu.

  22. Luku 19:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”

  23. Luku 19:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí.

  24. Luku 19:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.

  25. Luku 19:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’