Fò sí àkóónú

Leah

32 ẹsẹ · 10 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Leah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò.

  2. Àwọn ọmọ Lea, Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.

  3. Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea: Gadi àti Aṣeri. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.

  4. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀.

  5. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀.

  6. Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí.

  7. Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu.