Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sọ fún Mose pé,

  2. “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa.

  3. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.

  4. Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an, ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.

  5. “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.

  6. Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

  7. Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”

  8. Olúwa sọ fún Mose wí pé,

  9. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, àwọn àjọ̀dún ti Olúwa èyí tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún tí a yàn.

  10. “ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.

  11. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, àjọ̀dún tí a yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákokò wọn.

  12. Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.

  13. Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ni àjọ̀dún àkàrà àìwú tí Olúwa yó bẹ̀rẹ̀, fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.

  14. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.’ ”

  15. Olúwa sọ fún Mose pe,

  16. “Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.

  17. Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.

  18. Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa.

  19. Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan).

  20. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

  21. Ẹ ka àádọ́ta ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Olúwa.

  22. Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òsùwọ̀n ìdá méjì nínú mẹ́wàá tí efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí Olúwa.

  23. Ẹ fi akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí, wọn yóò jẹ́ ẹbọ sísun sí Olúwa, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu wọn, àní ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn ni sí Olúwa.

  24. Kí àlùfáà fi ọ̀dọ́-àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà.

  25. “ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”