God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run.
Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?”
Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.”
Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà.
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá.
Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.”
Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu.
Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.”
Sì kíyèsi i, wòlíì kan tọ Ahabu ọba Israẹli wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
Ahabu sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?” Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Nípa ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ àwọn ìjòyè ìgbèríko.’ ” Nígbà náà ni ó wí pé. “Ta ni yóò bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” Wòlíì sì dalóhùn pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”
Ènìyàn Ọlọ́run kan sì gòkè wá, ó sì sọ fún ọba Israẹli pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Nítorí tí àwọn ará Aramu rò pé Olúwa, Ọlọ́run òkè ni, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe Ọlọ́run àfonífojì, nítorí náà èmi ó fi gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí lé ọ lọ́wọ́, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”
Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú.
Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.
Ó sì wí fún ọba pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ ti jọ̀wọ́ ọkùnrin tí èmi ti yàn sí ìparun pátápátá lọ́wọ́ lọ. Nítorí náà, ẹ̀mí rẹ yóò lọ fún ẹ̀mí rẹ, ènìyàn rẹ fún ènìyàn rẹ̀.’ ”
Ṣùgbọ́n Naboti wí fún Ahabu pé, “Olúwa má jẹ́ kí èmi fi ogún àwọn baba mi fún ọ.”
Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú síwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí sí i wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí lòdì sí Naboti níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Naboti ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé,
Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”
Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.
‘Èmi yóò mú ibi wá sórí rẹ. Èmi yóò sì mú ìran rẹ kúrò, èmi yóò sì ké kúrò lọ́dọ̀ Ahabu gbogbo ọmọdé ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀, àti òmìnira ní Israẹli.
Èmi yóò ṣe ilé rẹ bí ilé Jeroboamu, ọmọ Nebati, àti bí ilé Baaṣa, ọmọ Ahijah, nítorí ìwọ ti mú mi bínú, ìwọ sì ti mú Israẹli ṣẹ̀.’
“Àti ní ti Jesebeli pẹ̀lú Olúwa wí pé, ‘Àwọn ajá yóò jẹ Jesebeli nínú yàrá Jesreeli.’
(Kò sí ẹnìkan bí Ahabu tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe búburú níwájú Olúwa, ẹni tí Jesebeli aya rẹ̀ ń tì.
Ó sì ṣe ohun ìríra gidigidi ní tí tọ òrìṣà lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí àwọn ará Amori ti ṣe, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.)