Fò sí àkóónú

Balaam

59 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Balaam

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Balaamu ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.

  2. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀.

  3. Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú.

  4. Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

  5. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Israẹli lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn ún lé wọn lórí. (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún.)

  6. Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

  7. Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo.

  8. Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Kaini, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìṣìnà Balaamu nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kora.

  9. Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.