Skip to content
Johanu 1:19-34

Johanu 1:19-34

19
Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.
20
Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”
21
Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?” Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.” “Ìwọ ni wòlíì náà bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22
Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23
Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24
Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán
25
bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”
26
Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi, ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀,
27
Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.
29
Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!
30
Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’
31
Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”
32
Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé, “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e.
33
Èmi kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’
34
Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options