Isaiah 28:1-15
1
Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.
2
Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
3
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
4
Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú, yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀, òun a sì mì ín.
5
Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, àti adé tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
6
Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́ àti orísun agbára fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.
7
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
8
Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
9
“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
10
Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí, ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
11
Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀ Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
12
àwọn tí ó sọ fún wí pé, “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”; àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”; ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
13
Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé, ṣe èyí, ṣe ìyẹn, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
14
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
15
Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings