Eksodu 12:42-51
42
Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní òru yìí ni gbogbo Israẹli ní láti máa ṣe àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀.
43
Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá: “Àjèjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀.
44
Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà,
45
ṣùgbọ́n àtìpó àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.
46
“Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀.
47
Gbogbo àjọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀.
48
“Àjèjì ti ó bá ń gbé ní àárín yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ilà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ilà, wọ́n kò ni jẹ nínú rẹ̀.
49
Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárín yín.”
50
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni.
51
Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings