Skip to content
2 Samuẹli 15:1-12

2 Samuẹli 15:1-12

1
Lẹ́yìn èyí náà, Absalomu sì pèsè kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin fún ara rẹ̀, àti àádọ́ta ọmọkùnrin tí yóò máa sáré níwájú rẹ̀.
2
Absalomu sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apá kan ọ̀nà ẹnu ibodè. Bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli wá.”
3
Absalomu yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ ṣá dára, ó sì tọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.”
4
Absalomu a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan bá à lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.”
5
Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ láti tẹríba fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dìímú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.
6
Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́, Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀.
7
Ó sì ṣe lẹ́yìn ogójì ọdún, Absalomu sì wí fún ọba pé, “Èmi bẹ́ ọ́, jẹ́ kí èmi ó lọ, kí èmi sì san ìlérí mi tí èmi ti ṣe fún Olúwa, ní Hebroni.
8
Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”
9
Ọba sì wí fún un pé, “Máa lọ ní àlàáfíà.” Ó sì dìde, ó sì lọ sí Hebroni.
10
Ṣùgbọ́n Absalomu rán àmì sáàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá gbọ́ ìró ìpè, kí ẹ̀yin sì wí pé, ‘Absalomu jẹ ọba ní Hebroni.’ ”
11
Igba ọkùnrin sì bá Absalomu ti Jerusalẹmu jáde, nínú àwọn tí a ti pè; wọ́n sì lọ nínú àìmọ̀kan wọn, wọn kò sì mọ nǹkan kan.
12
Absalomu sì ránṣẹ́ pe Ahitofeli ará Giloni, ìgbìmọ̀ Dafidi, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Giloni, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Absalomu.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options