2 Samuẹli 14:28-33
28
Absalomu sì gbé ni ọdún méjì ní Jerusalẹmu kò sì rí ojú ọba.
29
Absalomu sì ránṣẹ́ sí Joabu, láti rán an sí ọba, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá.
30
Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Joabu gbé ti èmi, ó sì ní ọkà barle níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tiná bọ oko náà.
31
Joabu sì dìde, ó sì tọ Absalomu wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tiná bọ oko mi?”
32
Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.”
33
Joabu sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un: ó sì ránṣẹ́ pe Absalomu, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Absalomu lẹ́nu.
Settings